Job 21:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ani nigbati mo ranti, ẹ̀ru bà mi, iwarìri si mu mi lara.

7. Nitori kini enia buburu fi wà li ãyè, ti nwọn gbọ́, ani ti nwọn di alagbara ni ipa!

8. Iru-ọmọ wọn fi idi kalẹ li oju wọn pẹlu wọn, ati ọmọ-ọmọ wọn li oju wọn.

9. Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn.

10. Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu;

11. Nwọn a ma rán awọn ọmọ wọn wẹwẹ jade bi agbo ẹran, awọn ọmọ wọn a si ma jó.

12. Nwọn mu ohun ọnà orin timbreli ati dùru, nwọn si nyọ̀ si ohùn ifère.

13. Nwọn lo ọjọ wọn ninu ọrọ̀; ni iṣẹjukan nwọn a lọ si ipo-okú.

14. Nitorina ni nwọn ṣe wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa, nitoripe awa kò fẹ ìmọ ipa ọ̀na rẹ!

Job 21