30. Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu.
31. Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe?
32. Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú.
33. Ogulutu ọfin yio dùn mọ ọ, gbogbo enia yio si ma tọ̀ ọ lẹhin, bi enia ainiye ti lọ ṣiwaju rẹ̀.
34. E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.