15. Kini Olodumare ti awa o fi ma sin i? ere kili a o si jẹ bi awa ba gbadura si i!
16. Kiyesi i, alafia wọn kò si nipa ọwọ wọn, ìmọ enia buburu jina si mi rére.
17. Igba melomelo ni a npa fitila enia buburu kú? igba melomelo ni iparun wọn de ba wọn, ti Ọlọrun isi ma pin ibinujẹ ninu ibinu rẹ̀.
18. Nwọn dabi akeku oko niwaju afẹfẹ, ati bi iyangbo, ti ẹfufu-nla fẹ lọ.
19. Ọlọrun to ìya-ẹ̀ṣẹ rẹ̀ jọ fun awọn ọmọ rẹ̀, o san a fun u, yio si mọ̀ ọ.
20. Oju rẹ̀ yio ri iparun ara rẹ̀, yio si ma mu ninu riru ibinu Olodumare.
21. Nitoripe alafia kili o ni ninu ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati a ba ke iye oṣù rẹ̀ kuro li agbedemeji?
22. Ẹnikẹni le ikọ́ Ọlọrun ni ìmọ? on ni sa nṣe idajọ ẹni ibi giga.
23. Ẹnikan a kú ninu pipé agbara rẹ̀, ti o wà ninu irọra ati idakẹ patapata.
24. Ọpọ́n rẹ̀ kún fun omi-ọmú, egungun rẹ̀ si tutu fun ọra.
25. Ẹlomiran a si kú ninu kikoro ọkàn rẹ̀, ti kò si fi inu didun jẹun.
26. Nwọn o dubulẹ bakanna ninu erupẹ, kòkoro yio si ṣùbo wọn.
27. Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi.
28. Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà?
29. Ẹnyin kò bere lọwọ awọn ti nkọja lọ li ọ̀na, ẹnyin kò mọ̀ àmi wọn? pe,
30. Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu.
31. Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe?
32. Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú.