Job 20:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye?

5. Pe, orin ayọ̀ enia buburu igba kukuru ni, ati pe, ni iṣẹju kan li ayọ̀ àgabagebe.

6. Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma.

7. Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà?

8. Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru.

9. Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́.

10. Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada.

11. Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ.

12. Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀.

Job 20