19. Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́.
20. Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ.
21. Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́.
22. Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori.
23. Yio si ṣe pe, nigbati o ma fi kún inu rẹ̀ yo nì, Ọlọrun yio fa riru ibinu rẹ̀ si i lori, nigbati o ba njẹun lọwọ.
24. Yio sá kuro lọwọ ohun-ogun irin, ọrun akọ-irin ni yio ta a po yọ.
25. O fà a yọ, o si jade kuro lara, ani idà didan ni njade lati inu orõro wá: ẹ̀ru-nla mbẹ li ara rẹ̀.
26. Okunkun gbogbo ni a ti pamọ́ fun iṣura rẹ̀, iná ti a kò fẹ́ ni yio jo o run: yio si jẹ eyi ti o kù ninu agọ rẹ̀ run.
27. Ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ rẹ̀ hàn, aiye yio si dide duro si i.
28. Ibisi ile rẹ̀ yio kọja lọ, ati ohun ini rẹ̀ yio ṣàn danu lọ li ọjọ ibinu Ọlọrun.
29. Eyi ni ipin enia buburu lati ọdọ Ọlọrun wá, ati ogún ti a yàn silẹ fun u lati ọdọ Oluwa wá.