Job 20:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a.

17. Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́.

18. Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀.

19. Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́.

20. Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ.

21. Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́.

22. Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori.

23. Yio si ṣe pe, nigbati o ma fi kún inu rẹ̀ yo nì, Ọlọrun yio fa riru ibinu rẹ̀ si i lori, nigbati o ba njẹun lọwọ.

24. Yio sá kuro lọwọ ohun-ogun irin, ọrun akọ-irin ni yio ta a po yọ.

25. O fà a yọ, o si jade kuro lara, ani idà didan ni njade lati inu orõro wá: ẹ̀ru-nla mbẹ li ara rẹ̀.

26. Okunkun gbogbo ni a ti pamọ́ fun iṣura rẹ̀, iná ti a kò fẹ́ ni yio jo o run: yio si jẹ eyi ti o kù ninu agọ rẹ̀ run.

27. Ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ rẹ̀ hàn, aiye yio si dide duro si i.

Job 20