1. NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe,
2. Nitorina ni ìro inu mi da mi lohùn, ati nitori eyi na ni mo si yara si gidigidi.
3. Mo ti gbọ́ ẹsan ẹ̀gan mi, ẹmi oye mi si da mi lohùn.
4. Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye?