6. Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka.
7. Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ.
8. O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi:
9. O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi.
10. O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi: