Job 19:3-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya.

4. Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami.

5. Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju.

6. Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka.

7. Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ.

8. O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi:

9. O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi.

10. O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi:

11. O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀.

12. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka.

13. O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ.

Job 19