Job 19:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi:

11. O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀.

12. Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka.

13. O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ.

14. Awọn ajọbi mi fà sẹhin, awọn afaramọ́ ọrẹ mi si di onigbagbe mi.

Job 19