1. NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe,
2. Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja?
3. Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya.
4. Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami.
5. Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju.
6. Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka.