6. Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de?
7. Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete.
8. Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju.
9. Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi.
10. Nwọn ti fi ẹnu wọn yán si mi, nwọn gbá mi li ẹrẹkẹ ni igbá ẹ̀gan, nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si mi.
11. Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ.
12. Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀.
13. Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ.