13. Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ.
14. Ibajẹ lori ibajẹ li o fi ba mi jẹ; o sure kọlù mi bi òmirán.
15. Mo rán aṣọ-apo bò ara mi, mo si rẹ̀ iwo mi silẹ ninu erupẹ.
16. Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi.
17. Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu.
18. A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan.
19. Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun.
20. Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun.