Job 15:2-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ọlọgbọ́n a ma sọ̀rọ ìmọ asan, ki o si ma fi afẹfẹ ila õrùn kún ara rẹ̀ ninu:

3. On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere?

4. Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun.

5. Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò.

6. Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ.

7. Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke?

Job 15