Job 15:19-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja.

20. Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara.

21. Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i.

Job 15