Job 14:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan!

5. Njẹ ati pinnu ọjọ rẹ̀, iye oṣu rẹ̀ mbẹ li ọwọ rẹ, iwọ ti pàla rẹ̀, bẹ̃li on kò le ikọja rẹ̀.

6. Yipada kuro lọdọ rẹ̀, ki o le simi titi yio fi pé ọjọ rẹ̀ bi alagbaṣe.

7. Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá.

8. Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ.

9. Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko.

10. Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da?

11. Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ.

12. Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn.

13. A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi.

Job 14