Job 14:18-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀.

19. Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo.

20. Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro.

21. Awọn ọmọ rẹ̀ bọ́ si ipo ọlá, on kò si mọ̀, nwọn si rẹ̀ silẹ, on kò si kiyesi i lara wọn.

22. Ṣugbọn ẹran-ara rẹ̀ ni yio ri irora, ọkàn rẹ̀ ni yio si ma ni ibinujẹ ninu rẹ̀.

Job 14