Job 14:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn.

13. A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi.

14. Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de.

15. Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ.

16. Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi.

17. A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀.

18. Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀.

19. Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo.

20. Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro.

21. Awọn ọmọ rẹ̀ bọ́ si ipo ọlá, on kò si mọ̀, nwọn si rẹ̀ silẹ, on kò si kiyesi i lara wọn.

Job 14