1. ENIA ti a bi ninu obinrin ọlọjọ diẹ ni, o si kún fun ipọnju.
2. O jade wá bi itana eweko, a si ke e lulẹ, o si nfò lọ bi ojiji, kò si duro pẹ́.
3. Iwọ si nṣiju rẹ wò iru eyinì, iwọ si mu mi wá sinu idajọ pẹlu rẹ.
4. Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan!