Job 13:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji.

10. Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ.

11. Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya?

12. Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀.

13. Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀.

Job 13