Job 11:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe,

2. A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ?

3. Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi?

4. Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ.

Job 11