Job 10:12-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Iwọ ti fun mi li ẹmi ati oju rere, ibẹ̀wo rẹ si pa ọkàn mi mọ́.

13. Nkan wọnyi ni iwọ si ti fi pamọ ninu rẹ; emi mọ̀ pe, eyi mbẹ lọdọ rẹ.

14. Bi mo ba ṣẹ̀, nigbana ni iwọ sàmi si mi, iwọ kì yio si dari aiṣedede mi ji.

15. Bi mo ba ṣe ẹni-buburu, egbé ni fun mi! bi mo ba si ṣe ẹni-rere, bẹ̃li emi kò si le igbe ori mi soke. Emi damu, mo si wo ipọnju mi.

16. Nitoriti npọ̀ si i: iwọ ndẹ mi kiri bi kiniun; ati pẹlu, iwọ a si fi ara rẹ hàn fun mi ni iyanju.

Job 10