18. Bi o ti nsọ li ẹnu, ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin njẹ nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin.
19. Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ.
20. Nigbana ni Jobu dide, o si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, o si fari rẹ̀, o wolẹ, o si gbadura.
21. Wipe, Nihoho ni mo ti inu iya mi jade wá, nihoho ni emi o si tun pada lọ sibẹ: Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa.
22. Ninu gbogbo eyi Jobu kò ṣẹ̀, bẹ̃ni kò si fi were pè Ọlọrun lẹjọ.