Job 1:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ.

11. Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.

12. Oluwa si dá Satani lohùn wipe: kiyesi i, ohun gbogbo ti o ni mbẹ ni ikawọ rẹ, kìki on tikara rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ rẹ kàn: bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa.

13. O si di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati obinrin njẹ, ti nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin:

14. Onṣẹ kan si tọ̀ Jobu wá wipe: awọn ọda-malu ntulẹ, awọn kẹtẹkẹtẹ si njẹ li ẹba wọn;

15. Awọn ara Saba si kọlu wọn, nwọn si nkó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn ti fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa, emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati ròhin fun ọ.

16. Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ.

17. Bi o si ti nsọ li ẹnu, ẹnikan si de pẹlu ti o wipe: awọn ara Kaldea pingun si ọ̀na mẹta, nwọn si kọlu awọn ibakasiẹ, nwọn si kó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn si fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa; emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati rohin fun ọ.

Job 1