Joṣ 21:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù.

27. Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji.

28. Ati ninu ẹ̀ya Issakari, Kiṣioni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Dabarati pẹlu àgbegbe rẹ̀;

29. Jarmutu pẹlu àgbegbe rẹ̀, Engannimu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.

30. Ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, Miṣali pẹlu àgbegbe rẹ̀, Abdoni pẹlu àgbegbe rẹ̀;

31. Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.

Joṣ 21