48. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
49. Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn:
50. Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀.
51. Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.