19. Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù.
20. Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn.
21. Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi;
22. Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli;
23. Ati Affimu, ati Para, ati Ofra;
24. Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn:
25. Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu;