1. JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.
2. Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri;
3. Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù: