6. Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.
7. Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.
8. Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:
9. Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.
10. Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan;
11. Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan;
12. Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan;
13. Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan;
14. Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;
15. Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan;
16. Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan;
17. Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan;
18. Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan;
19. Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan;
20. Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan;