Joṣ 11:15-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, bẹ̃ni Mose paṣẹ fun Joṣua: bẹ̃ni Joṣua si ṣe; on kò kù ohun kan silẹ ninu gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ fun Mose.

16. Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀;

17. Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.

18. Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀.

19. Kò sí ilu kan ti o bá awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ, bikoṣe awọn Hifi awọn ara ilu Gibeoni: gbogbo wọn ni nwọn fi ogun gbà.

Joṣ 11