10. Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe,
11. Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní.
12. Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe,
13. Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi.