16. Lati Dani ni a gbọ́ fifọn imu ẹṣin rẹ̀; gbogbo ilẹ warìri fun iro yiyan akọ-ẹṣin rẹ̀; nwọn si de, nwọn si jẹ ile run, ati eyi ti mbẹ ninu rẹ̀: ilu ati awọn ti ngbe inu rẹ̀,
17. Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi.
18. Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi!
19. Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu?
20. Ikore ti kọja, ẹ̀run ti pari, a kò si gba wa la!
21. Nitori ipalara ọmọbinrin enia mi li a ṣe pa mi lara; emi ṣọ̀fọ, iyanu si di mi mu.
22. Kò ha si ojiya ikunra ni Gileadi, oniṣegun kò ha si nibẹ? ẽṣe ti a kò fi ọ̀ja dì ọgbẹ́ ọmọbinrin enia mi.