11. Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi.
12. Ẹ si lọ nisisiyi, si ibujoko mi, ti o wà ni Ṣilo, ni ibi ti emi fi orukọ mi si li àtetekọṣe, ki ẹ si ri ohun ti emi ṣe si i nitori ìwa-buburu enia mi, Israeli.
13. Njẹ nisisiyi, nitori ẹnyin ti ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi, li Oluwa wi, ti emi si ba nyin sọ̀rọ, ti emi ndide ni kutukutu ti mo si nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́; ti emi si npè nyin, ṣugbọn ẹnyin kò dahùn.
14. Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo.
15. Emi o si ṣá nyin tì kuro niwaju mi, gẹgẹ bi mo ti ṣá awọn arakunrin nyin tì, ani gbogbo iru-ọmọ Efraimu.
16. Nitorina máṣe gbadura fun enia yi, bẹ̃ni ki o má si gbe igbe rẹ soke ati adura fun wọn, bẹ̃ni ki o má ṣe rọ̀ mi: nitori emi kì yio gbọ́ tirẹ.
17. Iwọ kò ha ri ohun ti nwọn nṣe ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu?
18. Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke.
19. Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn?
20. Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀.