39. Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi.
40. Emi o si mu wọn wá bi ọdọ-agutan si ibi pipa, bi àgbo pẹlu obukọ.
41. Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède!
42. Okun wá sori Babeli: a si fi ọ̀pọlọpọ riru omi rẹ̀ bò o mọlẹ.
43. Ilu rẹ̀ ni ahoro, ilẹ gbigbe, ati aginju: ilẹ ninu eyiti ẹnikẹni kò gbe, bẹ̃ni ọmọ enia kò kọja nibẹ.
44. Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó.
45. Enia mi, ẹ jade ni ãrin rẹ̀, ki olukuluku nyin si gba ẹmi rẹ̀ là kuro ninu ibinu gbigbona Oluwa!
46. Ati ki ọkàn nyin má ba rẹ̀wẹsi, ati ki ẹ má ba bẹ̀ru, nitori iró ti a o gbọ́ ni ilẹ na; nitori iró na yio de li ọdun na, ati lẹhin na iró yio de li ọdun keji, ati ìwa-ika ni ilẹ na, alakoso yio dide si alakoso.
47. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, ti emi o bẹ awọn ere fifin Babeli wò: oju yio si tì gbogbo ilẹ rẹ̀, gbogbo awọn olupa rẹ̀ yio si ṣubu li ãrin rẹ̀.