32. Ati pe, a gbà awọn asọda wọnni, nwọn si ti fi ifefe joná, ẹ̀ru si ba awọn ọkunrin ogun.
33. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u.
34. Nebukadnessari, ọba Babeli, ti jẹ mi run, o ti tẹ̀ mi mọlẹ, o ti ṣe mi ni ohun-elo ofo, o ti gbe mi mì gẹgẹ bi ọ̀wawa, o ti fi ohun didara mi kún ikun rẹ̀, o ti le mi jade.
35. Ki ìwa-ika ti a hù si mi ati ẹran-ara mi ki o wá sori Babeli, bẹ̃ni iwọ olugbe Sioni yio wi; ati ẹ̀jẹ mi lori awọn olugbe, ara Kaldea, bẹ̃ni iwọ, Jerusalemu, yio wi.
36. Nitorina bayi ni Oluwa wi; Wò o, emi o gba ijà rẹ jà, emi o si gba ẹsan rẹ, emi o si gbẹ okun rẹ̀, emi o si mu gbogbo orisun rẹ̀ gbẹ.
37. Babeli yio si di òkiti àlapa, ibugbe ọ̀wawa, iyanu, ẹsin, laini olugbe.
38. Nwọn o jumọ bú bi kiniun: nwọn o si ke bi ọmọ kiniun.
39. Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi.
40. Emi o si mu wọn wá bi ọdọ-agutan si ibi pipa, bi àgbo pẹlu obukọ.
41. Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède!
42. Okun wá sori Babeli: a si fi ọ̀pọlọpọ riru omi rẹ̀ bò o mọlẹ.
43. Ilu rẹ̀ ni ahoro, ilẹ gbigbe, ati aginju: ilẹ ninu eyiti ẹnikẹni kò gbe, bẹ̃ni ọmọ enia kò kọja nibẹ.
44. Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó.