Jer 51:26-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi.

27. Ẹ gbe asia soke ni ilẹ na, fọn ipè lãrin awọn orilẹ-ède, sọ awọn orilẹ-ède di mimọ́ sori rẹ̀, pè awọn ijọba Ararati, Minni, ati Aṣkinasi sori rẹ̀, yàn balogun sori rẹ̀, mu awọn ẹṣin wá gẹgẹ bi ẹlẹnga ẹlẹgun.

28. Sọ awọn orilẹ-ède pẹlu awọn ọba Media di mimọ́ sori rẹ̀, awọn balẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.

29. Ilẹ yio si mì, yio si kerora: nitori gbogbo èro Oluwa ni a o mú ṣẹ si Babeli, lati sọ ilẹ Babeli di ahoro laini olugbe.

30. Awọn akọni Babeli ti dẹkun jijà, nwọn ti joko ninu ile-odi wọn; agbara wọn ti tán; nwọn di obinrin, nwọn tinabọ ibugbe rẹ̀; a ṣẹ́ ikere rẹ̀.

31. Ẹnikan ti nsare yio sare lọ lati pade ẹnikeji ti nsare, ati onṣẹ kan lati pade onṣẹ miran, lati jiṣẹ fun ọba Babeli pe: a kó ilu rẹ̀ ni iha gbogbo.

32. Ati pe, a gbà awọn asọda wọnni, nwọn si ti fi ifefe joná, ẹ̀ru si ba awọn ọkunrin ogun.

33. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u.

Jer 51