1. Ẹrìn kiri la ita Jerusalemu ja, ki ẹ si wò nisisiyi, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si wakiri nibi gbigbòro rẹ̀, bi ẹ ba lè ri ẹnikan, bi ẹnikan wà ti nṣe idajọ, ti o nwá otitọ; emi o si dari ji i.
2. Bi nwọn ba si wipe, Oluwa mbẹ; sibẹ nwọn bura eke.
3. Oluwa, oju rẹ kò ha wà lara otitọ? iwọ ti lù wọn, ṣugbọn kò dùn wọn; iwọ ti run wọn, ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le jù apata lọ; nwọn kọ̀ lati yipada.
4. Emi si wipe, Lõtọ talaka enia ni awọn wọnyi, nwọn kò ni oye, nitori nwọn kò mọ̀ ọ̀na Oluwa, tabi idajọ Ọlọrun wọn.
5. Emi o tọ̀ awọn ẹni-nla lọ, emi o si ba wọn sọrọ; nitori nwọn ti mọ̀ ọ̀na Oluwa, idajọ Ọlọrun wọn. Ṣugbọn awọn wọnyi ti jumọ ṣẹ́ àjaga, nwọn si ti ja ìde.