Jer 49:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀?

2. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi.

3. Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀.

4. Ẽṣe ti iwọ fi nṣogo ninu afonifoji, afonifoji rẹ nṣan lọ, iwọ ọmọbinrin ti o gbẹkẹle iṣura rẹ, pe, tani yio tọ̀ mi wá?

5. Wò o, emi o mu ẹ̀ru wá sori rẹ, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, lati ọdọ gbogbo awọn wọnni ti o wà yi ọ kakiri; a o si le nyin, olukuluku enia tàra niwaju rẹ̀; ẹnikan kì o si kó awọn ti nsalọ jọ.

6. Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi.

7. Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi?

Jer 49