26. Ẹ mu u yo bi ọmuti: nitori o gberaga si Oluwa: Moabu yio si ma pàfọ ninu ẽbi rẹ̀; on pẹlu yio si di ẹni-ẹ̀gan.
27. Kò ha ri bẹ̃ pe: Israeli jẹ ẹni ẹlẹyà fun ọ bi? bi ẹnipe a ri i lãrin awọn ole? nitori ni igbakũgba ti iwọ ba nsọ̀rọ rẹ̀, iwọ a ma mì ori rẹ.
28. Ẹnyin olugbe Moabu! ẹ fi ilu wọnni silẹ, ki ẹ si mã gbe inu apata, ki ẹ si jẹ gẹgẹ bi oriri ti o kọ́ itẹ rẹ̀ li ẹba ẹnu ihò.
29. Awa ti gbọ́ igberaga Moabu, o gberaga pupọ, iṣefefe rẹ̀, ati afojudi rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati giga ọkàn rẹ̀.
30. Emi mọ̀ ìwa igberaga rẹ̀; li Oluwa wi: ṣugbọn kò ri bẹ̃; ọ̀rọ asan rẹ̀, ti kò le ṣe nkankan.
31. Nitorina ni emi o hu fun Moabu, emi o si kigbe soke fun gbogbo Moabu, lori awọn ọkunrin Kirheresi li a o ṣọ̀fọ.
32. Emi o sọkun fun àjara Sibma jù ẹkùn Jaseri lọ: ẹka rẹ ti rekọja okun lọ, nwọn de okun Jaseri: afiniṣe-ijẹ yio kọlu ikore eso rẹ ati ikore eso-àjara rẹ.
33. Ati ayọ̀ ati ariwo inu-didùn li a mu kuro li oko, ati kuro ni ilẹ Moabu; emi si ti mu ki ọti-waini tán ninu ifunti: ẹnikan kì o fi ariwo tẹ̀ ọti-waini; ariwo ikore kì yio jẹ ariwo ikore mọ.