Jer 48:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ.

3. Ohùn igbe lati Horonaimu, iparun ati idahoro nla!

4. A pa Moabu run; awọn ọmọde rẹ̀ mu ki a gbọ́ igbe.

5. Nitori ẹkun tẹle ẹkun ni ọ̀na igoke lọ si Luhiti: nitori ni ọ̀na isọkalẹ Horonaimu a gbọ́ imi-ẹ̀dun, igbe iparun, pe:

6. Ẹ sa, ẹ gbà ẹmi nyin là, ki ẹ si dabi alaini li aginju!

7. Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀.

8. Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.

9. Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀.

10. Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rẹ̀ duro kuro ninu ẹjẹ.

11. Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada.

12. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn.

Jer 48