17. Gbogbo ẹnyin ti o wà yi i ka, ẹ kedaro rẹ̀; ati gbogbo ẹnyin ti o mọ̀ orukọ rẹ̀, ẹ wipe, bawo li ọpa agbara rẹ fi ṣẹ́, ọpa ogo!
18. Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run.
19. Iwọ olugbe Aroeri! duro lẹba ọ̀na, ki o si wò; bere lọwọ ẹniti nsa, ati ẹniti nsala, wipe, Kili o ṣe?
20. Oju tì Moabu: nitori a wó o lulẹ: ẹ hu, ki ẹ si kigbe; ẹ kede rẹ̀ ni Arnoni pe: a fi Moabu ṣe ijẹ,
21. Idajọ si ti de sori ilẹ pẹtẹlẹ; sori Holoni, ati sori Jahasi, ati sori Mefaati,
22. Ati sori Diboni, ati sori Nebo, ati sori Bet-diblataimu.
23. Ati sori Kiriataimu, ati sori Bet-Gamuli, ati sori Bet-Meoni,
24. Ati sori Kerioti, ati sori Bosra, ati sori gbogbo ilu ilẹ Moabu, lokere ati nitosi.
25. A ke iwo Moabu kuro, a si ṣẹ́ apá rẹ̀, li Oluwa wi.
26. Ẹ mu u yo bi ọmuti: nitori o gberaga si Oluwa: Moabu yio si ma pàfọ ninu ẽbi rẹ̀; on pẹlu yio si di ẹni-ẹ̀gan.
27. Kò ha ri bẹ̃ pe: Israeli jẹ ẹni ẹlẹyà fun ọ bi? bi ẹnipe a ri i lãrin awọn ole? nitori ni igbakũgba ti iwọ ba nsọ̀rọ rẹ̀, iwọ a ma mì ori rẹ.
28. Ẹnyin olugbe Moabu! ẹ fi ilu wọnni silẹ, ki ẹ si mã gbe inu apata, ki ẹ si jẹ gẹgẹ bi oriri ti o kọ́ itẹ rẹ̀ li ẹba ẹnu ihò.
29. Awa ti gbọ́ igberaga Moabu, o gberaga pupọ, iṣefefe rẹ̀, ati afojudi rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati giga ọkàn rẹ̀.
30. Emi mọ̀ ìwa igberaga rẹ̀; li Oluwa wi: ṣugbọn kò ri bẹ̃; ọ̀rọ asan rẹ̀, ti kò le ṣe nkankan.