Jer 48:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SI Moabu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Egbe ni fun Nebo! nitoriti a fi ṣe ijẹ: oju tì Kiriataimu, a si kó o: oju tì Misgabu, o si wariri.

2. Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ.

3. Ohùn igbe lati Horonaimu, iparun ati idahoro nla!

4. A pa Moabu run; awọn ọmọde rẹ̀ mu ki a gbọ́ igbe.

5. Nitori ẹkun tẹle ẹkun ni ọ̀na igoke lọ si Luhiti: nitori ni ọ̀na isọkalẹ Horonaimu a gbọ́ imi-ẹ̀dun, igbe iparun, pe:

6. Ẹ sa, ẹ gbà ẹmi nyin là, ki ẹ si dabi alaini li aginju!

7. Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀.

8. Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.

Jer 48