Jer 47:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori ọjọ na ti mbọ lati pa gbogbo awọn ara Filistia run, ati lati ke gbogbo oluranlọwọ ti o kù kuro lọdọ Tire ati Sidoni: nitori Oluwa yio ṣe ikogun awọn ara Filistia, ani iyokù erekuṣu Kaftori.

5. Ipári de si Gasa, Aṣkeloni ti dahoro, pẹlu iyokù afonifoji wọn: iwọ o ti ṣa ara rẹ lọgbẹ pẹ to?

6. Ye! iwọ idà Oluwa, yio ti pẹ to ki iwọ ki o to gbe jẹ? tẹ ara rẹ bọ inu akọ rẹ, simi! ki o si dakẹ!

7. Ṣugbọn bawo li o ti ṣe le gbe jẹ, nigbati Oluwa ti paṣẹ fun u si Aṣkeloni, ati si ebute okun, nibẹ li o ti ran a lọ!

Jer 47