Jer 43:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Jeremiah pari ọ̀rọ isọ fun gbogbo awọn enia, ani gbogbo ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun wọn, eyiti Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a si wọn, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

2. Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ:

3. Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neriah, li o fi ọ̀rọ si ọ li ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kaldea lọwọ, lati pa wa ati lati kó wa ni igbekun lọ si Babeli.

Jer 43