Jer 40:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, lẹhin ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti ranṣẹ pè e lati Rama. Nitori nigbati o mu u, a fi ẹwọn dè e lãrin gbogbo awọn igbekun Jerusalemu ati Juda, ti a kó ni ìgbekun lọ si Babeli.

2. Balogun iṣọ si mu Jeremiah, o si wi fun u pe, Oluwa, Ọlọrun rẹ, ti sọ ibi yi si ilu yi.

3. Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin.

4. Njẹ nisisiyi, wò o, mo tú ọ silẹ li oni kuro ninu ẹ̀wọn ti o wà li ọwọ rẹ: bi o ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, kalọ, emi o boju to ọ: ṣugbọn bi kò ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, jọwọ rẹ̀; wò o, gbogbo ilẹ li o wà niwaju rẹ, ibi ti o ba dara ti o ba si tọ li oju rẹ lati lọ, lọ sibẹ.

5. Bi bẹ̃kọ, pada tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilu Juda, ki o si mã ba a gbe lãrin ọpọ enia, tabi ibikibi ti o ba tọ li oju rẹ, lati lọ, lọ sibẹ̀. Balogun iṣọ si fun u li onjẹ ati ẹbun; o si jọ́wọ́ rẹ̀ lọwọ.

6. Jeremiah si lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ni Mispa; o si mba a gbe lãrin awọn enia, ti o kù ni ilẹ na.

Jer 40