Jer 37:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SEDEKIAH, ọmọ Josiah si jọba ni ipo Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ẹniti Nebukadnessari, ọba Babeli, fi jẹ ọba ni ilẹ Juda.

2. Ṣugbọn ati on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia ilẹ na, kò fetisi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa Jeremiah, woli.

3. Sedekiah, ọba si ran Jehukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Ṣefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, si Jeremiah woli, wipe: Njẹ, bẹbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun wa fun wa.

4. Jeremiah si nwọle o si njade lãrin awọn enia: nitori nwọn kò ti ifi i sinu tubu.

5. Ogun Farao si jade lati Egipti wá: nigbati awọn ara Kaldea ti o dótì Jerusalemu si gbọ́ iró wọn, nwọn lọ kuro ni Jerusalemu.

6. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah, woli wá, wipe,

7. Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti.

8. Awọn ara Kaldea yio si tun wá, nwọn o si ba ilu yi jà, nwọn o kó o, nwọn o si fi iná kún u.

Jer 37