31. Emi o si jẹ on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ niya, nitori aiṣedede wọn; emi o si mu wá sori wọn, ati sori awọn olugbe Jerusalemu, ati sori awọn ọkunrin Juda, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn, ṣugbọn nwọn kò gbọ́.
32. Nigbana ni Jeremiah mu iwe-kiká miran, o si fi i fun Baruku, akọwe, ọmọ Neriah; ẹniti o kọwe sinu rẹ̀ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ iwe ti Jehoiakimu, ọba Juda ti sun ninu iná: a si fi ọ̀rọ pupọ bi iru eyi kún ọ̀rọ iwe na pẹlu.