5. Iwọ o kú li alafia: ati bi ijona-isinkú awọn baba rẹ, awọn ọba igbãni ti o wà ṣaju rẹ, bẹ̃ni nwọn o si ṣe ijona-isinkú fun ọ, nwọn o si pohunrere rẹ, pe, Yẽ oluwa! nitori eyi li ọ̀rọ ti emi ti sọ, li Oluwa wi.
6. Jeremiah woli, si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun Sedekiah, ọba Juda ni Jerusalemu.
7. Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.
8. Ọ̀rọ ti o tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa lẹhin ti Sedekiah, ọba, ti ba gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu dá majẹmu, lati kede omnira fun wọn.
9. Pe, ki olukuluku enia le jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia, iranṣẹbinrin rẹ̀, ti iṣe ọkunrin Heberu tabi obinrin Heberu, lọ lọfẹ; ki ẹnikẹni ki o má mu ara Juda, arakunrin rẹ̀, sìn.
10. Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ.