5. Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi.
6. Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn.
7. Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju.
8. Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi.