Jer 33:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá lẹ̃keji, nigbati a si se e mọ ninu agbala ile túbu, wipe,

2. Bayi li Oluwa wi, ẹniti o ṣe e, Oluwa, ti o pinnu rẹ̀, lati fi idi rẹ̀ mulẹ; Oluwa li orukọ rẹ̀;

3. Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.

4. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ile ilu yi, ati niti ile awọn ọba Juda ti a wó lulẹ ati nitori odi ati nitori idà;

Jer 33